Skip to content

Latest commit

 

History

History
306 lines (153 loc) · 23 KB

yoruba.md

File metadata and controls

306 lines (153 loc) · 23 KB

BBC News Yorùbá

Natasha lulẹ̀ níwájú ìgbìmọ́ aṣòfin, wọ́n da ẹ̀sùn ìyọlẹ́nu fún ìbálòpọ̀ tó fi kan Akpabio nù

Ọjọ́rú, 5 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 13:21:45

Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìwà ọmọlúàbí ní ilé aṣòfin àgbà da ẹjọ́ ti Natasha pè tako Akpabio nù lọ́jọ́rú, wọ́n ní ẹ̀sùn rẹ̀ kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

Àìsàn ẹ̀jẹ̀ rúru ló kọ́ ṣe 'I Sho Pepper'', ó ń pọ̀ ẹ̀jẹ̀ lórí ahọ́n, dákú fọ́jọ́ mẹ́sàn -án, kí ọlọ́jọ́ tó dé - Yetunde Ogunsola

Ọjọ́bọ, 6 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 08:58:55

Ọdun 1972 ni Yetunde Ogunsola to jẹ ọmọbibi ilu Ilesha bẹrẹ ere tita lẹyin to darapọ mọ ẹgbẹ oṣere oloogbe ''I Sho Pepper.''

Wo àwọn àìsàn tó le ṣúyọ ní àgọ́ ara lásìkò ààwẹ̀

Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 11 Oṣù Ìgbé 2023 ní 06:13:59

Lásìkò àwẹ̀, àwọn ènìyàn máa ń séra fún oúnjẹ jíjẹ, omi mímu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àmọ́ ẹ wo àwọn àrùn tó le ti ìdí ààwẹ̀ súyọ.

Ọ̀gá tẹ́lẹ̀ fún iléeṣẹ́ arìnrìnàjò tí ayé ń kígbe pé Boko Haram pa, ilé ìtura ló kú sí l'Abuja - Ọlọ́pàá

Ọjọ́bọ, 6 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 05:48:09

Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa fun ilu Abuja, Josephine Adeh, buwọ lu, tẹsiwaju pe ko pẹ ti Parradang wọ yara rẹ ni alejo obinrin kan wa a ki i.

'Àwọn agbéṣùmọ̀mí lẹ́kùn Sahel Africa ló ń ṣekúpa èèyàn jù lágbàáyé'

Ọjọ́rú, 5 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 16:46:06

Ẹkùn Sahel ní Afirika ní ìdá mọ́kànléláàádọ́ta (51%) nínú ìdá ọgọ́rùn-ún ikú látara ìgbéṣùmọ̀mí ti wáyé lọ́dún 2024.

Ìgbésẹ̀ láti káwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò ní ìwé ìgbélùú l'Amẹrika padà wálé, ti bẹ̀rẹ̀ tipẹ́ - Mínísítà

Ọjọ́rú, 5 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 12:19:39

Ọgbẹni Tuggar sọ pe igbesẹ kiko awọn ọmọ Naijiria ti ko niwe igbelu ti bẹrẹ ṣaaju ki Aarẹ Donald Trump to wọle ibo aarẹ Amẹrika fun saa keji.

BBC fojú ṣe mẹ́rin bí wọn ti ń ṣàtúnṣe wáyà ojú òpó ìtàkùn àgbáyé tó bá bàjẹ́ lábẹ́ òkun

Ọjọ́rú, 5 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 11:26:46

BBC dara pọ mọ awọn osisẹ ileesẹ to n satunse kebu itakun agbaye to wa labẹ okun Ghana lati mọ bi wọn ti n se atunse awọn kebu inu okun naa.

Ìdí rèé tí Jandor ṣe fi PDP sílẹ̀ àti ohun tó mú kó kùnà láti dojú Sanwo-Olu bolẹ̀ lásìkò ìbò gómìnà l‘Eko

Ọjọ́rú, 5 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 12:00:40

Jandor sọrọ yii lori eto ileeṣẹ tẹlifisan kan lalẹ ọjọ Iṣẹgun amọ o ti kede saaju pe oun ti fi ẹgbẹ oselu PDP silẹ.

Zelensky ṣèlérí láti ṣèpàdé àlááfíà pẹ̀lú Trump lẹ́yìn tí wọn pariwo mọ́ ara wọn

Ọjọ́rú, 5 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 08:19:59

Aarẹ Volodymyr Zelensky loun kabamọọ ihuwasi oun lasiko itakurọsọ to waye laarin oun ati Donald Trump nileeṣẹ ijọba Amẹrika.

Makinde yan Eleruwa tí wọ́n yọ nípò padà lẹ́yìn ọdún mẹ́fà

Ọjọ́rú, 5 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 08:13:55

Atẹjade ti Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilaniloye nipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade, fi sita lo fidi eyi mulẹ.

Ó ṣeéṣe kí ìdajì àwọn èèyàn tó wà láyé sanra àsanjù tó bá fi máa di ọdún 2050

Ọjọ́rú, 5 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 06:30:37

Èyí ló ń jẹyọ nínú àbọ̀ kan tí àjọ The Lancet ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde lórí ìwádìí tí wọ́n ṣe ní àwọn orílẹ̀ èdè tó lé ní igba.

UN figbe ta pé àwọn agbébọn ń fipá bá àwọn ọmọ ọdún kan lo pọ lásìkò ogun abẹ́lé ní Sudan

Ọjọ́rú, 5 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 06:09:53

Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN, lati ọdọ ẹka rẹ to n ri si ọrọ ọmọde; UNICEF, ni àwọn agbébọn ń fipá bá àwọn ọmọ ọdún kan lo pọ ni Sudan.

Iléepo Dangote àti NNPC bẹ̀rẹ̀ orogún òwò lórí àdínkú owó líta epo, wo àwọn tí orí ń ta

Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 11:22:17

Ọpọ awọn alagbata epo lo sọ pe ileeṣẹ NNPCL ko tii sọ fawọn pe adinku ti ba iye tawọn yoo maa ta epo fawọn bayii.

Ìjàm̀bá okọ̀ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́rìndínlógún ní Ogun

Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 17:08:41

Nǹkan bíi aago kan ọ̀sán ni ìjàm̀bá náà wáyé nígbà tí ọkọ̀ Mazda kan tó ní nọ́mbà KJA949YJ ṣàdédé gbiná.

Darapọ̀ mọ́ wa lórí WhatsApp

Ọjọ́ Ajé, 15 Oṣù Ìgbé 2024 ní 11:20:59

Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ

Ọlọ́pàá yabo ibùba ajínigbé, ọwọ́ tẹ afúrasí mẹ́rin pẹ̀lú ohun ìjà olóró

Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 12:45:36

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo, DSP Okoye Henry, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita.

Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi, Ayodele Fayose ń yan odì ọ̀lọ́jọ́ pípẹ́, bí a kò bá sọ̀rọ̀ láyé, á pàdé lọ́run - Isaac Fayose

Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 09:39:35

BBC Yorùbá bá Isaac, tíí ṣe àbúrò gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose sọ̀rọ̀, ó ṣàlàyé àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ìdí tó ṣe ní aya àti ọmọ púpọ̀ pẹ̀lú ètò ìṣèlú.

Wo èèwọ̀ kékèké tí o kò mọ̀ pé ó le ba Ramadan jẹ́

Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 12:20:48

Onimọ ni awọn nnkan miran wa tawọn eeyan ro pe o le ba aawẹ jẹ, ṣugbọn to jẹ wọn ko ṣe akoba kankan fun aawẹ.

Ìwádìí BBC rèé lórí bí ojú òpó TikTok ṣe ń fi ìhòhò àwọn ọmọdé pawó

Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 12:15:56

A ba awọn obinrin mẹta sọrọ lorilẹede Kenya, wọn si fidi ẹ mulẹ fun wa pe awọn ti bẹrẹ si i fi ihoho awọn han loju opo naa nigba ti ọjọ ori awọn ṣi wa laaarin mẹẹẹdogun si mọkandinlogun.

Ta ló ń ro ikú ro Olubadan tí ariwo ikú rẹ̀ fi gbalẹ̀ kan?

Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 07:15:19

Kọmiṣọnna fun aṣa ati irinajo igbafẹ nipinlẹ Oyo, Wasiu Olatubosun ti fidi rẹ mulẹ pe iroyin ofege ni iroyin naa, o ni koko lara Olubadan le bi ọta.

Ariwo sọ bí ìpínlẹ̀ mẹ́rin lókè ọya ṣe ti ilé ẹ̀kọ́ pa f‘óṣù kan torí ààwẹ̀ Ramadan, CAN fọnmú

Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 10:51:24

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ Aiku ọsẹ yii ni Aarẹ CAN, Arcbishop Daniel Okoh ti ṣapejuwe igbesẹ naa bii iwa aitọ si awọn akẹkọọ ti ki i ṣe Musulumi.

''Mo fi ara mi sílẹ̀ fáwọn ajínigbé nígbà tí wọ́n fẹ́ máa mú ìyàwó mi lọ''

Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 12:29:51

Olabiyisi ẹni ọdun mọkandinlọgbọn lawọn ẹṣọ Amotekun doola lakata awọn ajinigbe lẹyin wakati mẹẹdogun ti wọn ti jigbe.

Mo jẹ́rìí aya mi lórí ẹ̀sùn tó fi kan Akpabio, mo ti rọ̀ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé kó fi aya mi lọ́rún silẹ̀ - ọkọ Natasha

Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 16:04:06

Atẹjade ti Uduaghan fi sita ni oun ko fẹ da si ọrọ naa tẹlẹ ṣugbọn awọn nnkan to n jade lori rẹ, lo jẹ ki oun tẹnu bọ ọrọ.

NLC kéde ìwọ́de yíka Nàìjíríà tí ìjọba bá ṣe àfikún owó iná míì

Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 06:45:09

Ninu atẹjade kan to fi sita lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ NLC niluu Yola ni ipinlẹ Adamawa lopin ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ naa ti ṣapujewe erongba ijọba lati ṣe afikun owo ina mọnamọna gẹgẹ bi igbesẹ ti ko dara fawọn oṣiṣẹ ati fun gbogbo araalu.

Afurasí oníṣòwò lu ìyàwó rẹ̀ pa lórí oúnjẹ ààwẹ̀ Ramadan, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 08:05:26

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Ahmed Wakil, sọ pe lalẹ ọjọ Abamẹta opin ọsẹ to kọja ni iṣẹlẹ yii waye lagbegbe Fadamam Mada ni Bauchi.

Hisbah mú àwọn ọ̀dọ́ tó ń jẹ ọ̀sán lásìkò ààwẹ̀ Ramadan

Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 07:08:21

Lọdun 2024, eeyan mọkanla ni ikọ Hisbah mu lórí ẹsun pe wọn n jẹun ọsan nilu Kano.

Èyí lohun tíjọba sọ nígbà tí mo dá mílíọ̀nù púpò tí mo rí he padà - Muibi Shonubi

Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 17:15:44

Muhibi ṣalaye iru idẹyẹsi to foju ri latọdọ awọn alabaṣiṣẹ rẹ gẹgẹ bi awakọ.

Wọ́n gbé gbogbo àwọn obínrin lọ - Àwọn obìnrin tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ lọ́gbà ẹ̀wòn DR Congo sọ ìrírí wọn

Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 12:40:15

Oun ni ọkunrin keji ti yoo fipa balopọ ninu ọgba ẹwọn Munzenze ree. O daku lasiko ti akọkọ waye.

Wọ́n tẹ èèyàn méje pa lásìkò tí wọn fẹ́ gba nǹkan ààwẹ̀

Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 06:41:25

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Bauchi ni lọjọ keji aawẹ Ramadan ni awọn ero to pọ naa ti bẹrẹ si ti ara wọn, nibẹ si ni eeyan mẹrin ti kọkọ dagbere faye.

Àlàyé rèé lórí bí Mudasiru Obasa ṣe padà di olórí ilé aṣòfin Eko

Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 17:45:05

Ọnarebu Noheem Adams to n ṣoju ẹkùn Eti-Osa lo fa Obasa kalẹ pe ki wọn dibo fun un, Ọnarebu Nureni Akinsanya lati Mushin si ṣe ikeji aba naa.

Ìdí tí mo fi fẹ́ gbé Babangida lọ ilé ẹjọ́ lórí ìwé tó kọ - Falana

Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 11:49:48

Femi Falana sọ pe Ibrahim Babangida fagile eto lati da ijọba pada fun alagbada ni igba mẹrin ọtọtọ pẹlu agbekalẹ ofin ologun nọmba 25 to ṣe lọdun 1987.

Lẹ́yìn ìwádìí BBC, NAFDAC fòfin de àwọn òògùn iléeṣẹ̀ Aveo tí wọ́n ń tà ní Naijiria

Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 15:19:13

Ninu atẹjade kan ti alaga Ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye ni NAFDAC ko fi igbakankn se akọsilẹ fun oogun Tafrodol tabi Royal 225 tabi Tramadol gan .

Ọpọlọ ọkùnrin tí iná jó títí tó fi ku, paradà di gíláàsì

Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 06:37:01

Iwọn gilaasi ti wọn ri ni ọpọlọ rẹ jẹ iwọn sẹntimita kan si meji, ti awọn kan si jẹ iwọn milimita.

Ọwọ́ iléeṣẹ ọlọ́pàá tẹ bàbá tó gbá ọmọ rẹ̀ ní ìpá ni Ogun

Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 17:58:48

Ikede yii lo jade loju opo ayelujara agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi lọjọ Ṣatide.

Ẹ̀mí sùn, ọ̀pọ̀ dúkìà ṣòfò níbi ìjàmbá tánkà agbépo àti tírélà n'Ilorin

Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 09:00:15

Ileesẹ panapana ipinlẹ Kwara ṣalaye ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Ileesẹ naa, Hassan Hakeem Adekunle, fi lede pe iwadii awọn fi han pe tirela to ko ajilẹ naa lo fẹ ya tanka epo ọhun lati ẹyin sugbọn ti o kọ lu u lẹgbẹ.

Ansoogun ògbóǹtarìgì jagunjagun Iresa Adu l'Ogbomoso 'tó bínú di òkúta pẹ̀lú àwọn ẹrú rẹ̀'

Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 09:05:42

Oloye James Olawale salaye pe gbogbo nkan ti wọn fi n bọ oriṣa Ogun naa ni wọn fi n bọ Apata Ansoogun bii aja, epo, ẹmu, obi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bí o ṣe lè máa ka ìròyìn BBC Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Ọjọ́ Ajé, 24 Oṣù Èrèlè 2025 ní 13:43:55

Ni bayii, ẹ le ri iroyin yajoyajo, iroyin lori nnkan to n lọ atawọn iroyin lori iṣẹlẹ lawujọ ti BBC Yoruba ṣe akojọpọ rẹ lori foonu yin.

Kókó ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Tinubu sọ lórí àwẹ̀ Ramadan tó bẹ̀rẹ̀

Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Ẹrẹ̀nà 2025 ní 12:45:36

Aarẹ Bola Tinubu ni ''awẹ Ramadan ọdun yii ṣe pataki tori o bọ si asiko ti eto ilọsiwaju ati ireti tuntun n lọ lọwọ ni Naijiria.''